ÀWỌN ỌDỌ ORÍLÈ-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ TI SEETÁN LATI GBA ARA WON KÚRÒ LỌ́WỌ́ ÒṢÈLÚ "BÀBÀ-SOPÉ'"..Gbadebo Rhodes-Vivour.
Nise ni ó má ń jó mi lójú tí mo ba n gbọ bí àwọn ènìyàn ṣe n ṣe owo ìlú basu basu ti ijoba ko si gbe igbese kankan lati fi iya je won,abi kini ka tí gbọ wipe èèyàn-kan fí owo ti o koja ọgbọ́n bilionu ra geeti asi wọle jáde sí ilé rẹ,geeti tí kò lè gbéni dẹ ọrùn rere,!!.Gbadebo Rhodes tí ó je oludije fún ipo gomina labẹ Asia ẹgbẹ oselu Labour party ninu idibo 2023 ti o koja lo fi ehonu rẹ hon nínú ifọrọwerọ kan tí ó ṣe pẹlu ẹgbẹ àwọn oniroyin LYMP ni ile rẹ lopin ọsẹ tí ó kọjá yii.
Odomokunrin, akíkanjú olóṣèlú yii ko sai sọ bí ọkàn òun ṣe gbọgbẹ pẹlu ìwà tí àwọn Oniṣẹṣe ipinle Eko wu nígbà idibo tí ó kọjá nípa gbígbé orò jáde ní àsìkò idibo láti ṣe atilẹyin fún ondijedupo ọmọ ẹgbẹ oselu APC nígbà náà lohun kí ó lè bá jawe olùbori labẹ akooso bí ó ṣe wù kó rí..
O ni irúfé ìwà báyìí ko ni jẹ ki awon èwe tí ó ń bo lẹyin gbagbọ ninu àṣà àti ìṣe ile Yoruba mo nítorí nise ni wọn yio ma ro wípé ẹṣin Iṣẹṣe wa fún láti má ṣègbé fún àwọn "morolayo ajifa" àti jagidijagan
O tun tẹ síwájú nípa bí àwọn àgbà Oniṣẹṣe ìwòyí ṣe n pa ifá tí,tí wón sì ń fi ẹni tí ó bá wù wọn jẹ ọba lé ara ilu lórí,ní èyí tí kò sì ṣe bẹẹ so èso rere fún ara ilu.
Arákùnrin Gbadebo tun so nípa bí gbogbo ara ilu ṣe n pariwo ebi ń pa wa kiri ṣùgbọ́n tí ó je wipe ohun tí ó je omo aarẹ orile-ede Naijiria ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Seyi Tinubu lógún ni bí yio se wa di gomina ipinle Eko ni èyí tí ó sì jẹ wipe ìpinnu yii gan ni ó ń fà ruke rúbọ tí ó ń ṣẹlẹ̀ ninu ile igbimọ aṣofin ipinle Eko.
O ni ohun tí ó yani lẹnu ni ki a tun ma rí kí ọmọ aarẹ orilẹ ede yii ma sáré sókè sodo látàrí pé òun je gomina nipinlẹ Eko pẹlu bi baba rẹ ti o je Aare ko se ri ohun gidi kan gbese láti yọ orile-ede èdè tí ó je aarẹ lè ló kúrò nínú iya àti ìṣe tí ó wà.
Ṣáájú ni ondije dupe gomina fún ẹgbẹ oṣelu Labour party yii ti kọkọ lu àwọn odò orile-ede Naijiria lógo ẹnu látàrí bí wọn ṣe jade tan ninu idibo tí ó kọjá lai ni ìrètí láti gba ohunkóhun rọ́pò padà lọwọ ẹnikẹ́ni ju ijọba tí yio se ara ilu lanfaani tí yio si fi kaluku lọkan balẹ lo.
O fi kún ọrọ rẹ pé irú atilẹyin bayii ni ohun ko ti rí rí latijo tí ohun tí bẹrẹ sini ṣe oselu,ní eyii ti o si fi da ohun lójú wipe yatọ si pe awọn ọdọ Naijiria ti setan fún igbare ẹni lọwọ oselu jegudujera àti amunisin wọn tun ti setan fún ètò oṣelu tí yíò mú ìyípadà ńlá ba àgbò oselu orile-ede èdè Nàìjíríà nibi ti ko si ni si"baba -sọpe 'mọ.
Comments
Post a Comment