ÌFẸ́ ÀISÈTÀN TÍ MO NÍ SÍ ÀṢÀ ÀTI ÌṢE LÓ SỌ MÍ DI ỌBALEFUN ÌJỌ OLÓRÌSÀ PARAPÒ.....Gbadebo Rhodes-Vivour

              
 
      L'enu kope-kope  yii ni wọn fi oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, nipinlẹ Eko, Gbadebọ Rhodes-Vivour,  joye Ọbalẹfun ijọ oloriṣa parapọ ni ilu Badagry ni ipinle Eko. 
       Nise ni gbọngan ootẹli Ayabot Events Centre, to wa lọna Ado-Odo, Badagry, nipinlẹ Eko, kun fọfọ fun awọn  otokulu ilu lọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun yii, ti  akíkanjú olóṣèlú ọhun di Obalẹfun.
     Ògọ̀rò eeyan gẹgẹ bi awon oloṣelu,onisowo, atawọn eeyan pataki lawujọ to fi mọ awọn oniṣẹṣe lo peju pese lati waa ṣayesi baba Oloye tuntun ọhun lọjọ naa.
    Nígbàtí agba  ọjẹ nidii iṣẹ ayaworan ile ọhun  n ba awon akọròyìn sọ̀rọ̀  lo salaye wipe  won fi  ohun je oyè Ọbalẹfun ati aṣoju alaafia ijọ Oloriṣa Parapo naa nítorí igbagbọ ati ife aisetan ti awón ìjọ naa gbagbọ wipe  ohun ni si aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba.
      O fi kún ọrọ rẹ pé, oye naa ko si fun iru wa ogiri wa bi ko ṣe f'ẹni to ba jẹ ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba, to si n fi gbogbo ọjọ aye rẹ wa  ilọsiwaju fun,ọmọ, asa,àti ìṣe ilẹ Yoruba 
        Oloye tuntun ọhun tẹ síwájú lati salaye bi o se je omo yoruba atata ti o si ni ife si ohunkóhun ti o ba rọ mo Yoruba ati ise re ,o fi kún pe ,pẹ̀lú gbogbo agbára  ohun lo n fi ma n wa ìtànkalẹ ati ìdàgbàsókè si ohunkóhun ti o ba ti jọmọ asa ati ise yoruba.
         Oloye Gbadebọ salaye wipe ko si nnkan to buru ju ninu ki a gbe awọn òrìṣà wa larugẹ bii ogun, Ifa,osanyin,sango,obatala,oya, atawọn ooṣa mii in larugẹ nitori iṣẹmbaye ni wọn,awọn si ni a gbonju mọ. 
         O salaye wipe gẹgẹ bi ẹni ti a bi ni àárín gbùngbùn ilu Eko, ni ojule kejidinlogoji,agbegbe Igboṣere ni isale Eko, nibi ti wọn ti pada fi kọ City Hall lonii ẹsẹ ni fun ohun ti ohun ba fi ọwọ yẹpẹrẹ mu asa ati ise ile yoruba nítorí agbegbe yii gan-an ni awon asa ati ise ipinlẹ Eko sodo si ,ni èyí tí awon si gbonju mọ dáadáa.
      O tun salaye bi asa se je atona fun iwa ọmọlúwàbí, eyi to nii ṣe pẹlu orukọ rere, tí o si n múni duro lori àdéhùn,ni eyii ti ohun ni ìgbàgbó wipe awon olóṣèlú orilẹ-ede yii lílò lásìkò ti ètò òṣèlú ti di yánpọnyánrin bayii.
     Lákòótán ni o wa sọ bi inu ọpọlọpọ oba ilẹ Yoruba pàápàá julo Oba Ọjaja  ilẹ ifẹ, Ọọni Adeyeye Ogunwusi ṣe fi ìdùnnú rẹ han si titewo ti ohun tẹwọ gba oye Ọbalẹfun lọwọ àwọn ijọ Oloriṣa parapọ̀ yii,nítorí o gbagbọ wipe èyí yíò tun ran ipolongo asa àti ìṣe lọwọ láàárín àwọn ọdọ ilẹ Yoruba 

Comments

Popular posts from this blog

Ọmọlúwàbí Stakeholders Pay Courtesy Visit to Aregbesola, Reaffirm Loyalty to ADC Ideals

APC Chieftain Odukoya Adeyinka Sefiu Resigns, Cites Failed Promises and Unfair Treatment.

FROM BLACKOUT TO BRIGHT LIGHTS: How Dr. Naheem Balogun Rewrote Epe’s Story