ÌJÀ L'ÓDÉ L'ORÍN D'ÒWE,KÉKERÉ KỌ́ NI ÀTÌLẸ́YÌN TÍ Ọ̀GBẸ́NI RAUF ARẸ́GBẸ́ṢỌLÁ ṢE FÚN ÀÀRẸ BỌ́LÁ TINUBU NÍGBÀ TÓ ṢE GÓMÌNÀ ÈKÓ......ALÁBÀÁṢIṢẸ́PỌ̀

      Okan ninu awon alabasisepo Ogbeni Rauf Aregbesola,ni o ti salaye wipe  Ọpelọpẹ  Ogbeni Rauf Aregbesola,Muiz Banire,ati bẹẹ bẹẹ lọ lo je ki Aare Bola Tinubu se àṣeyọrí ipo gomina ti o se ni ipinle Eko nigba naa lọhun-un 
      O ni nígbà isejoba ti a n wi yii,ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu awon Kọmiṣanna ti o ni akíkanjú yii lo fi gbogbo emi wọn sin gómìnà teleri ọhun ti wọn si ri wipe awon pese ohun amayederun si ipinlẹ Eko ni yanturu ti o si je ki gbogbo èniyàn gba fun Tinubu gẹgẹ bi Gómìnà ti o gbóhúnjẹ fẹgbẹ ti o si gba àwo bọ. 
      O ni lasiko yii gẹgẹ bi Kọmiṣanna Aregbesola gbìyànjú lati se awon  òpópónà ti o dara si ọpọlọpọ ibi ti àwọn eniyan ko lero wipe ona le de rara ni igba odun si akoko ti a wa yii
O wa tan imole si ọpọlọpọ àhesọ ti awon eniyan n sọ nipa arákùnrin ọhun,o ni iro pátápátá ni wipe Aarẹ Bola Tinubu ni o ko ni iṣẹ Oṣelu ati wipe ki i ṣe ohun ni o fi oruko rẹ silẹ fun ipo minisita labẹ isejoba Muhammadu Buhari .
          Arákùnrin naa so wipe ko tile si lorilẹ-ede ede Naijiiria nigba ti Aarẹ ana ohun tikalara re fi fonu pe lati wálé ni kíákíá nítorí ohun fẹ fi ṣe minisita fun eto ọrọ abẹle 
     Nigba ti,eni ọrọ ṣ'ojú ẹ yii tẹ síwájú ninu alaye rẹ ni o wipe ki Ogbeni Aregbesola to lo si oke òkun rara ni o ti kọkọ ko awon iwe àṣeyọrí rẹ ti o ṣe e gbani ṣiṣẹ lo síwájú Tinubu wipe a kii mọ ti wọn yio ba fe loo fun ipeni si ipo minisita
       O ni Aarẹ Bola Tinubu, kọ lati gba lọwọ rẹ pelu alaye wipe eyii ti o se to,ki o fun elomi laaye nítorí awon ko le lọ mọ, ni èyí tí ó je ki Ogbeni ko awon iwe rẹ ti o si gba oke okun lo ki eleda to wa pada ṣe e loore latọwọ Aarẹ ana.

Comments

Popular posts from this blog

Ọmọlúwàbí Stakeholders Pay Courtesy Visit to Aregbesola, Reaffirm Loyalty to ADC Ideals

APC Chieftain Odukoya Adeyinka Sefiu Resigns, Cites Failed Promises and Unfair Treatment.

FROM BLACKOUT TO BRIGHT LIGHTS: How Dr. Naheem Balogun Rewrote Epe’s Story