ÌṢ'AGBÀRALÒ : ỌLỌPAA DÍ Ọ̀NÀ PA NÍT'ORÍ WỌN KÒ FẸ KÍ ẸGBẸ́ ADC SE'POLONGO ÌBÒ NÍ'JÈBÚ.

    Àìgbọra-eniyé kan fẹ bẹ silẹ nibi ìpolongo atundi ibo sí ilé ìgbìmò asofin agba l'oni ọjọ kẹrìnlá oṣù kẹjọ odun 2025 ni ilu Rẹmo ni ipinlẹ Ogun nígbà tí àwọn Ọlọpaa kò láti jẹ ki arákùnrin Solomon Osho bá àwọn alatileyin re sọrọ.
      Ni kété tí ijọba ipinlẹ Ogun ti gbo wipe Ogbeni Rauf Aregbesola tí wó ipinle ọhun láti wá ṣe atilẹyin fún ohundije-dupo Solomon Ọṣhọ tí ó jáde láti inú ẹgbẹ ADC ni ó ti fi ọpọlọpọ awọn Olopaa sọwọ sì gbogbo ibi tí ó mọ wipe o seese ki arákùnrin náà tí ṣe ìpolongo ibo rẹ.
     Nise ni àwọn Ọlọpaa tí ó lè ní ogójì náà di kàkà di kuku bí ẹni tí ó ń rẹ ojú Ogun pelu moto akotanmi  oriṣiiriṣii ti wọn ko si oju ọna bí ìgbà tí Ogun bá wọ ìlú kí ó má bá sì ẹnikẹni ti yio gbé moto tẹle oludije náà láti polongo. 
   
    Ṣáájú ,ni àwọn Ọlọpaa tí ó tó bí ogójì ,tí kọkọ pàdé àwọn ogunlogo èrò tí ó tẹle ohundije dupo náà ni ilu Iṣara, tí ó je ilu abínibí rẹ,tí wón sì kó jalè wipe ko  le ri ìpolongo kankan ṣe nítorí wipe ,awon ti gba ìpè láti òkè wa ,wipe ẹnikẹni ko gbodo ṣe ìpolongo ibo kankan, yatọ si ẹgbẹ APC ni ilu naa ,ni ọjọ́ náà.
   Eyii ti o wa jẹ Kàyéfì ju ni wipe, nise ni àwọn Ọlọpaa tí ó di ìhámọ́ra ogun yii ,to àga, tábìlì, kalopi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ di gbogbo oju títí tí ó lọ láti ilu Iṣara lọ sí Ijebu Rẹmo, tí wón sì kó jalè wipe àṣẹ tí àwọn gba ni wípé kí ẹnikẹ́ni ma ṣe gba ọna náà kọjá. 
    Ọpelọpẹ Ogbeni Rauf Aregbesola, tí o pa láṣẹ fún àwọn olopa naa, nígbà tí ọkọ akọ- wọọrin rẹ dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ naa, wipe kíá mosa kí wón kó àwọn 'panduku" tí wón kó sì ojú ọna kúrò ,kí wón sì jẹ ki olúkúlùkù bá tìrẹ lọ, nítorí wipe títí ijọba ni wọn ti n fa idaduro ,ko si si ẹni ti o tọ fún wọn ní irúfé àṣẹ bẹ́ẹ̀.
     Logan ,tí àwọn Ọlọpaa náà f'oju kan Ogbeni Rauf ni wọn ti kọ ojú ibon wón silẹ ,tí wón sì bẹrẹ si ni ko gbogbo ohun tí wón kó sì ọna tẹ́lẹ̀ láti da Oludíje-dupò náà àti àwọn ènìyàn rẹ dúró kúrò lona, tí olúkúlùkù sí gba ìlú Rẹmo lo.
    Ìyàlẹ́nu ńlá ló tun wa jẹ́ fún gbogbo ènìyàn tí  ó tẹle alàgbà Ọṣhọ ,nígbà tí wón tun de gbàgede ibi ti o yẹ ki wọn ti ṣe ìpolongo náà tí wón sì tún rí ọpọlọpọ ọlọpaa ti wọn ti dúró togun-togun tí wón sì tún yari kanle wipe sẹẹ, ìpolongo ibo náà ko ni waye nitori àṣẹ tí ó wà láti òkè ni wipe ki awon ma ṣe fún ẹgbẹ miran laaye láti ṣe ìpolongo ibo ni oni ọjọ ,Ọjọbọ, Oṣù Kẹjọ ,odun 2025 ,ni ibi kankan ní agbegbe Ìjẹ̀bú nítorí ẹgbẹ APC nikan ni àwọn mọ tí ó fi ìpolongo sì ọjọ náà .
    Nígbà tí akọròyìn ilé iṣẹ wa fi oro wa Oga Ọlọpaa tí ó kó àwọn ọmọ iṣẹ rẹ sòdí wa si ibi ìṣẹ̀lẹ̀ naa ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fred Ode léèrè wipe kini ìdí pàtàkì tí àwọn Ọlọpaa fi pọ rẹpẹtẹ tibọn-tibọn nibi ìpolongo ibo tí wón sì kọ jalè fún arákùnrin Solomon láti polongo ibo ni ó salaye wipe, àṣẹ tí àwọn gba l'átòkè  ni wipe ẹgbẹ oselu méjì kó lè ṣe ìpolongo ibo ni ojo kan náà,àsìkò kan-na àti ní ibi kan-na ni èèkàn ṣoṣo.
  Ìdáhùn ọkùnrin DPO yii lo wa mu ki aķọròyìn wa tẹ síwájú nípa ibere rẹ wipe kilo wà ṣẹlẹ̀ tí wón  ko fi  jẹ ki oludije dupò náà tí kuku dúró ní ìlú Iṣara tí wón ti kọkọ wa lè kúrò lati se ìpolongo rẹ̀, ṣùgbọ́n nise ni ọkùnrin Ọlọpaa náà fi ìbínú kúrò laarin awọn eniyan, ti o si n tẹnu mo wipe,àṣẹ tí ohun gba lati  oke wa ni ki ẹnikẹ́ni tàbí ẹgbẹ kegbe  mase ṣe ìpolongo kánkán yatọ si ẹgbẹ APC, ti ko si si ohun ti ẹnikẹ́ni lè ṣe sii.

Comments

Popular posts from this blog

Ọmọlúwàbí Stakeholders Pay Courtesy Visit to Aregbesola, Reaffirm Loyalty to ADC Ideals

APC Chieftain Odukoya Adeyinka Sefiu Resigns, Cites Failed Promises and Unfair Treatment.

FROM BLACKOUT TO BRIGHT LIGHTS: How Dr. Naheem Balogun Rewrote Epe’s Story