YORUBA NI ÈYÀ TÍ Ó NÍ ÌGBÀGBÓ NÍNÚ ÌṢÒKAN NÀÌJÍRÍÀ JÙ NÍ ORÍLÈ-ÈDÈ YÌÍ....Sẹnetọ Anthony Adefuye
Sẹnetọ Anthony Adefuye ni akọwe agba fun ẹgbẹ Iṣọkan ,ile Yoruba.Lẹnu kope-kope yii ni awon akọròyìn ṣe abewo sì bàbá ọhun látàrí isejoba dẹmokiresi tí ó ń lọ lọwọ nítorí bàbá naa jẹ ọkan gbòógì ninu àwọn tí ó já fún ìjọba dẹmokiresi ni orile-ede Naijiria.
Nígbà tí bàbá Adefuye yíò bẹrẹ ọrọ ni ó kọkọ fi ìdùnnú rẹ han si bi Ọlọ́run Eledumare ṣe pada fi ààyè gba aarẹ Bola Ahmad Tinubu gẹgẹ bi aarẹ ọmọ Yoruba àkókò tí ó jẹ ni orile-ede Naijiria lẹyin ọpọlọpọ ìdúróṣinṣin àti aforiti tí àwọn ọmọ Yoruba ti ni lati ìgbà tí orile-ede èdè Nàìjíríà tí gba ominira lọ́wọ́ ìjọba ológun.
Sẹnetọ Anthony ko sai mẹ́nu bá diẹ ninu ìṣòro tí ìjọba ológun da silẹ l'orílè-èdè Naijiria nígbà tí wón n ṣe àkóso,ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ lọ, wọn fii ọpẹ fún Eledua tí ó ti gba Nàìjíríà pada láti bi ọdún mẹẹẹdọgbọn seyin lọwọ Ológun.
Wọn kò sàì ṣalaye wipe loootọ orile-ede Naijiria ko i tí de ibi ti gbogbo ọmọ Naijiria ni afojusun kí ó ti dé ní irú asikoyi ṣùgbọ́n wọn fi ìrètí wọn han wipe laipe yii a o de ibi tí a ń lò nítorí wipe diẹ diẹ ní
Ninu ifọrọwerọ yii, ni Sẹnetọ Anthony tí ṣalaye bi àwọn ẹ̀yà ọmọ Yoruba tí dúró ṣinṣin ninu ìgbàgbó wọn nípa Iṣọkan orile-ede Nàìjíríà tí wón sì kọ jalè láti lọ ní ilo tiwọn, ni gbogbo ìgbà tí ẹ̀kọ ko ba ṣe bẹẹ ṣe ojú mímu ni orile-ede yii.
Bàbá ni, a ó rántí wípé ìgbà kan ni àwọn ẹ̀yà ibo da ẹgbẹ́ Biafira silẹ tí wón sì ń fi da orile-ede láàmú látàrí wipe won gbagbọ wipe eto ijoba alasepo yii ko bawọn lára mú
Bakannaa, ọpọlọpọ ìgbà ni àwọn kan ti dìde ní ilé Haúsá tí wón n sọ ara won ni oriṣiiriṣii orúkọ,tí wón sì ń kọjú ija si awọn ẹ̀yà mìíràn bi ó tilè jẹ wipe awon ni wọn wa lori aleefa, tí ìní lára náà pọ to bẹẹ gẹẹ fún ọmọ Yoruba láti ṣe ìpinnu pe ki olúkúlùkù kó ẹkọ ẹ dání loootọ,ṣùgbọ́n, tí àwọn àgbàlagbà ilé Yorùbá,ma n fi gbogbo igba ,pẹ̀tù sí àwon ọmọ lẹyin wọn lọ́kàn ,pé kò sí ohun tí ó dára tó àlàáfíà àti Iṣọkan orile-ede Naijiria.
Sẹnetọ Anthony, ko sàì fẹnu kan bí ìjọba àpapò ṣe ni làti fi kún owo oṣù àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, kí ó bá le to wọn náà,wọn salaye wipe owo imú relé ni ipari oṣù gbọdọ jẹ owo ti o se gb'ale,tí ó lè bọ ìyàwó àti ọmọ, tí ó sì gbọdọ le rán ọmọ ni ile ìwé, ni eyii tí àwọn ko si ro wípé àádọ́rin naira lè ṣe rara.
Wọn wípé, ó ṣe pàtàkì láti tọju mẹkunnu tí ó bá ń ṣíṣe fún ni,nítorí ẹni tí èèyàn bá fún ni owo ti ko rerin,ó ti di dandan kí ó ṣe isé ti kọ rẹrin-in fún ni, ní èyí tí ko si ni jẹ ki orile-ede ṣe bẹẹ tẹ síwájú.
Lákòótán, Sẹnetọ Adefuye wa pé àkíyèsí ìjọba àpapò sì ìlànà ìfinijoyè àti ìfinijoba kaakiri ilẹ̀ Yoruba,nítorí àwọn ìwà tí kò yẹ kí a ba lọwọ ara ìlú, ni a má ń bá lọwọ àwọn ọba mìíràn ni ilé Yorùbá ni èyí tí ó sì ma n jẹ kí àwọn ènìyàn fẹ ma n fi ojú yẹpẹrẹ wo ipò Oríadè ilé Yorùbá.
Comments
Post a Comment