ĘSĘ KÒ GBÈRÒ NÍBI AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ÌYÀWÓ ỌGBẸNI RAUF ARẸGBẸṢỌLA NI ÌLÚ ÈKÓ.
Fọfọ ni ile akowe agba fun ẹgbẹ́ Africa Democratic Congress (ADC),Ogbeni Rauf Aregbesola kun fun ebi,ara,ore,olóṣèlú ati ọpọlọpọ afenifere ni ojo kerindinlogbo osu kẹsàn-án odun 2025(26/9/2025) nigba ti wọn n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi odun karundinlaadorin (65)fun iyawo won Alhaja Sherifat Abidemi.
Funfun lęyę n su,ni ọpọlọpọ awọn alejo wọ wa si ibi ìnáwó ohun ti ọpọlọpọ si gę gele ati fila alawọ oronbo ti o ti pọn le lori,ti wọn si n korin ọjọ ibi oniran-n-ran fun ọlọjọ ibi ohun.
Ṣẹṣẹ ni inu iya naa n dun ti wọn si n fi terin-tòyàyà n ki gbogbo awon ti o wa ba wọn ṣe ayẹyẹ orikadun ohun kaabo si gbagede ayẹyẹ náà.
Ọpọlọpọ awọn afenifere ni o n wole ni méje-mejọ pelu oriṣiiriṣii ẹ̀bùn lọwọ, ti akara oyinbo si n pe ara won ran niṣẹ ni onípele si ipele.
Ninu ọrọ idupe Alhaja Sherifat ni won ti kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun ti o je ki ọjọ ayẹyẹ náà ba awọn laye ati laaye rere,ti won si dúpẹ́ lọwọ gbogbo àwọn tí ó wa síbi ayẹyẹ náà nítorí ko si ìkéde ati ìpolongo fun ìnáwó ọhun, nise ni àwọn kan fi ṣe ìròyìn àtęnudénu ní èyí tí ó jẹ ki o jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu bi ẹsẹ ko se gbèrò níbi ayẹyẹ náà.
Ninu ọrọ ti wọn,ni ògbẹni Arẹgbẹṣọla náà ti dupẹ lọwọ Ọlọrun ọba gẹgẹ bi iyawo wọn,tí wọn si dupẹ lọwọ obìnrin naa fun gbogbo aduroti ti wọn n ṣe fun awọn ni gbogbo igba.
OgbeniAregbesola salaye wipe ọjọ ori iyawo awon kọ ló se koko si awọn bi ki i se ayọ̀, ìdùnnú ati alafia ti ọjọ́ orí náà má n mú dání wa fún obiran naa lọ́dọọdún ati pàápàá julo ibasepo ti o lọọrin ti Ọlọ́run n jẹ kí o fi ojojumo má a rinlẹ ninu ebi wọn.
Comments
Post a Comment