ÈYÍ GAN NI ÌDARAPÒ TI YÓÒ YỌ ORÍLÈ-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ NÍNÚ OKO ẸRÚ .....Gbadebo Rhodes-Vivour
Oludije ibo fun ipo gomina ninu ẹgbẹ Labour party ninu idibo 2023 ti o koja ni ipinle Eko Oloye Gbadebo Rhodes-Vivour ,ti d'igba d'agbon rẹ, o si ti kọri sinu ẹgbẹ Oselu African Democratic Congress bayii.
Oloselu naa fi ero re yii sita ninu ayẹyẹ kan ti o waye ni ilu Eko ni ojo Satide ti o koja yii.
A ó rántí wípé ọpọlọpọ alágbára ninu oselu Naijiria ni o ti pale mo eru wọn kuro ninu awon egbe ti wọn wa tẹlẹ bi ẹgbẹ APC ,PDP,ACCORD ati beebee lo lati lọ dara pọ mọ ẹgbẹ ADC pẹlu igbagbọ wipe won yóò jọ ja ajagbara lati gba ìjọba orilẹ-ede Nàìjíríà kuro lọwọ ẹgbẹ APC ti o n dari re lọ́wọ́.
Nigba ti Rhodes-Vivour n sọrọ, ni o kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun ti o je ki ojo naa wa saye,o salaye wipe bi eniyan ba gesin ninu ohun ko le kọṣe latari bi inu ohun ṣe dun to lati darapọ mọ ẹgbẹ ADC.
O ni ohun gba a ladura wipe ki Ọlọrun fun awọn alakoso ati agba ẹgbẹ ADC ni ọgbọ́n, imọ ati oye ti wọn yio fi ko ọmọ Nàìjíríà de ebute ogo.
Oloselu ohun ko sai bẹ gbogbo awon agba ẹgbẹ ati adari ẹgbẹ ADC lati wa ni isokan saaju idibo odun 2027 nitori ile ti o ba pin yẹlẹyẹlẹ ko ni le doju kọ ẹgbẹ APC
Ninu ọrọ tire,ni alaga fun ẹgbẹ ADC ni ipinle Eko,arakunrin George Ashiru ti ki oloselu Gbadebọ kaabo sinu ,ẹgbẹ ADC ti o si salye wipe pẹlu inu didun ni awon fi gba oloye Rhodes-Vivour sinu ẹgbẹ ADC nitori lati gbara ti wọn ti pari idibo 2023 ni awon ajọṣopọ ọrọ kọọkan ti n lọ labẹlẹ laari ohun ati ẹgbẹ Labour party ti inu ohun si dun jọjọ wipe Oluwa pada fi ọwọ si ajosepo ti ohun gbagbọ wipe yio so eso rere ohun.
Comments
Post a Comment