ONA ARA NI ARABA ILU OJOKORO GBE ODUN ISESE 2025 GBA NI ILU EKO
Ogunjo Oṣù Kẹjọ odun 2025 ni odun iṣẹṣe waye kaakiri ile Yoruba ni èyí tí gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, ololajulo Olusola Sanwo Olu si fun awọn ẹlẹ́sìn iṣẹṣe ni ìsinmi lọjọ naa.
A o ranti wipe bi odun mewa sẹ́yìn ni agbarijo awon oniṣẹṣe agbaye ti n gbe poyi ẹnu wipe o se pataki ki ijoba àpapò ya gbogbo Ogunjo Oṣù Kẹjọ silẹ fun awọn oniṣẹṣe lati ma ni ìsinmi nibi iṣẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ma n fun awọn elesin musulumi ati kirisiteni ni gbogbo igba ti wọn ba n ṣe ọdún tiwọn
Lóòótọ́ ijoba àpapò ko i tí fi ountẹ lu wipe ki awon ẹlẹ́sìn ìbílè ma ni ìsinmi lọjọ odun wọn, ṣùgbọ́n awon gómìnà kọ̀ọ̀kan ile Yoruba gẹgẹ bi Gómìnà, Eko,Osun ati bẹẹ bẹẹ lọ ti ya ogunjo Oṣù Kẹjọ silẹ fun ìsinmi ojo odun esin abalaye.
Bi eniyan ba g'eşin nínú Araba Ojokoro Oloye Ifawemimo Ayinde Ajanaku lọjọ Ọdún ti o koja yii koda ko le kọṣe nítorí nise ni inu baba náà ń dùn bi ojú gbogbo ọmọ,ẹbi,ara ,ọrẹ ati awon amuludun loriṣiiriṣii ṣe pé sibi ayẹyẹ náà.
Ilu Osodi tí Olóyè Àjànàkú tí jẹ alágbàáà fun gbogbo awọn eleegun ni gbogbo eto ti kọkọ bẹrẹ, bí elèégún ṣe n jade pẹlu oriṣiiriṣii ẹkù ni àwọn ẹlẹsa eleegun náà ń kí ẹsa eégún wọn ni méje mẹjọ,ka ma puro odun ọhun dùn,ó tún ní gbangban nínú,
Oriṣiiriṣii awọn olorin ibile lọ fi orin asa ati ise dára lọjọ naa, ti asọ ẹbi alára bara sì ń pe ara wọn niṣẹ.Bí wọn ṣe n ṣe, ni wọn nsọ, ó fé lè má sì iru ohunje tí wón kó ṣe tán lọjọ ti a n wi yíi.
Ọpọlọpọ awọn eeyan jankan jankan ni ó wà fi ijoko yẹ Agba òye Ifawemimo sì ni ojo ti a n wi yii,ti won si n fi ìdùnnú wọn han si gbogbo eto ti o lọ lẹsẹ-sẹ lojo náà.
Logan to Olóyè Ayinde ṣe ojúṣe wọn tan gẹgẹ bi alágbàáà gbogbo Osodi ni baba náà tẹ ọkọ létí ti o tun di ìlú Ojokoro nibi ti baba náà tí jẹ òye Araba,nibi yii gan wa ni pẹpẹyẹ ti pọn ọmọ tí ẹsẹ ko si gba èrò.
Ninu ọrọ idupe agba òye ọhun ni wọn ti dupe lọwọ gbogbo àwọn tí wón wá bawo ṣe odun ti wọn si fi àdúrà sì wọn wipe láṣẹ Èdùmàrè àwọn yóò tun jọ peju ṣe eléyìí tí ó ń bọ̀ ni.
Comments
Post a Comment