Òsèlú Àkőyawő Ni n O Se Ní Ìpínlè Ọṣun Tí Mo Ba Di Gomina ni Odun 2026.....Najeem Salaam


Omowe Najeem Folasayo Salaam, ti o je Ohundíje-dupò gomina ni ipinle Osun labẹ Asia ẹgbẹ ADC ni o ti salaye wipe òṣèlú akoyawọ ni ohun ti o se kókó lookan aya ohun ti ẹlẹ́dàá ba se ohun loore lati de ipo gomina nipinlẹ  Osun.
    Oloye Oluomo ilu Ejigbo,ti o je ilu kan pàtàkì ni ipinle Osun salaye idi pataki ti oun fi ni lati se Òṣèlú ti yio moju to gbogbo eka ijoba ti o wa ni ipinlẹ Osun nígbà ti oun ba akọròyìn ilé iṣẹ Ayekooto magazine sọrọ ni ilu Osogbo, ni ojo kerindinlogbon, Osu Kejila odun 2025 nigbati o lọ ṣe ifọrọwerọ lori bi eto Òṣèlú ipinlẹ Osun se n lo.
     Nigbati ti Oloye Salaam n te ṣíwájú ninu oro rẹ̀ ni o tẹnu mo idi pataki ti o fi yẹ ki gbogbo eka ijoba ni ipinlẹ kọọkan se se pàtàkì fun awọn ohunsejoba,o ni bi ẹni ti o je gómìnà ba se n moju to eka eto ọgbin, be lo ṣe yẹ ki o ma moju to ti iṣẹ ijoba,bi o ba se n moju to iṣẹ ijoba lo yẹ ki o ma moju to ile iṣẹ ti o n pese ohun amayerorun fun ilu,bi gomina ba se n moju to eto ẹ̀kọ́, bẹẹ lọ se yẹ ki o ma moju to eto ilera ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni èyí tí ohun si ti setan lati se fun gbogbo olùgbé ipinle Osun ti àwọn ènìyàn ipinlẹ Osun ba dibo fun ohun.
     Dokita Najeem tun salaye bi o se se pàtàkì ki eniyan ni iwa ti o dara laarin ilu,nitoripe Iwaloye ti awon eniyan tẹ mọ ohun lara je Orukọ ti awon ènìyàn so ohun látàrí, iwa rere ati iwa pele ti Eledumare fi jogun fun ohun l'atorun ti o si n fi gbogbo igba tọ isise aye ohun.
    Bakannaa ni ohundije-dupo ọhun tẹnu mo wipe ara idi pataki ti ohun fi jade dupo gómìnà ipinle Osun labẹ asia ẹgbẹ Òṣèlú ADC ni wipe,ati omode ati agba ipinlẹ Osun, yatọ si awon omo egbe ADC ni o n fi gbogbo ìgbà laago ikede si eti ohun wipe asiko ti to lati jade wa tuko ipinle Osun  lo sibi ire.
    Omowe Fiwasoye ko sai rọ awon ara ilu lati ma teti si awon ti wọn yio ko owo jade nigba ti Òṣèlú ba rinlẹ tan lati fi ra okan wọn, nitori iya odun mẹrin ni yio pada jasi fun wọn. 
     O tę síwájú ninu oro re pe,ohun gbogbo ti o wọn gogo báyìí,lati ori iresi de ori epo betiro le pada walę dáadáa tí ará ilu ba dibo fun Olori rere ti o gba wipe ojuse ohun ni lati se dáadáa fun ara ilu,yatọ fun awọn olori ti o ro wípé ohun ti o ba wu awọn lawon le ṣe fun awọn ohundibo.

Comments

Popular posts from this blog

Ọmọlúwàbí Stakeholders Pay Courtesy Visit to Aregbesola, Reaffirm Loyalty to ADC Ideals

APC Chieftain Odukoya Adeyinka Sefiu Resigns, Cites Failed Promises and Unfair Treatment.

FROM BLACKOUT TO BRIGHT LIGHTS: How Dr. Naheem Balogun Rewrote Epe’s Story