Ìmọtaraeni-nìkan àwọn Olóṣèlú ló fa Ìwà Ọdaju tí àwọn Ọdọ Orile-ede yii n hu báyìí...Oloye Ọlabọde George


Olóyè Ọlabọde Ibiyinka George tí ó je okan gbòógì nínú àwọn àgbà Oloselu orile-ede Naijiria ni ó ti ké gbàjarè wipe ìwà Imotaraeni nìkan,adanikanjopon,ojú kòkòrò àti ọpọlọpọ ìwà idoti miran ti àwọn olórí oloṣelu orile-ede Naijiria ń hù ní o fa ti àwọn ọdọ náà ṣe sọ ìwà ipá àti ipaniyan di àṣà .
    Olóyè Ibiyinka tí ó fi aidunnu rẹ han nípa orisirisi ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekú pani ti o ti wa di tọrọ fọn kalẹ ni orile-ede Naijiria nigbati ti o n ba awon oniroyin sọrọ nínú ilé rẹ ti o wa ni agbegbe Ikoyi ni ó fi vidio ti o n lọ kaakiri orí ayélujára kan ṣe apẹrẹ bí ìwà odaju àti ipaniyan ṣe wá di mẹta eepini laarin awọn ọdọ Nàìjíríà. 
   Olóyè náà salaye bi ọwọ awon agbofinro se tẹ odomokunrin kan ti o ge orí aburo rẹ ti o si fẹ lo ta fún àwọn tí ó ń rà ẹ̀yà ara ènìyàn kì ọwọ to tẹ ti àwọn agbofinro náà sì pa láṣẹ láti gbé orí aburo rẹ naa sórí kí ó sì má fi ẹnu rẹ̀ ka ohun tí ó ṣe.
    Bakannaa ni Olóyè George kò sai mẹ́nu kan bí àwọn kan ṣe tún ya wọ ipinlẹ Kwara ti wọn si pa awọn eniyan lọ bi ilé bí ẹni, ó salaye wipe ibi ti awon ọdọ bá ti gboju gbóya pa eeyan ti o le ni Ọgọrun leekan ṣoṣo lai kí ṣe ẹran, kí i ṣe orile-ede mọ, nise lo yẹ kí àwọn àgbàlagbà ibẹ tètè pé ara wọn jọ láti bá ara wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.
     Olóyè ti o je okan gbòógì nínú àwọn àgbà ẹgbẹ PDP yii ko sai  salaye bi o se je ohun ìyàlẹ́nu fún pe orile-ede Naijiria lè dédé bá ara rẹ ní irú ipò tí ó wà yìí laarin asiko ti ẹgbẹ PDP gbé ijoba silẹ àti sí asiko ti Aarẹ Bola Tinubu gba ìjọba.
      Baba naa salaye bi ebi àti ìṣe ṣe pawopo sọ àwọn ọdọ orile-ede Naijiria di ẹni tí kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run mọ ti wọn si n fi ojojumo gba omijé lójú àwọn ènìyàn bi tiwọn kiri.O wipe púpò nínú àwọn ọdọ Òkè Ọya ti o lọ sí ilé ìwé ṣugbọn ti ko ri ìṣe kánkán ṣe lẹyin ti wọn ba jade ni wọn ma n ko ara wọn jọ láti má dá ìlú láàmú,nitoripe ojú ti o dile ni irore ń sọ.
       Bakannaa ni alàgbà Ibiyinka bù ẹnu ate lù bi àwọn oloṣelu ṣe má ń wùwà bamu-bamu ni mo yọ lójú àwọn ọmọ tálákà,ó salaye wipe ọpọlọpọ ìgbà ni àwọn olóṣèlú má ń fi owó ti o yẹ ki kí wón fi ṣe ohun amayederun si ilu kí gbogbo mẹkunnu jegbadun kọ àwọn ilé ńláńlá ti ẹnìkan kò lè gbé káàkiri àgbáyé ti àwọn ìròyìn yìí sí ń bọ̀ si eti àwọn ọdọ yìí.
     Alàgbà Bode George wa gba àwọn adari Naijiria ni ìmọ̀ràn wipe asiko ti to lati pa ni dandan fun gbogbo gomina láti ṣe eto ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ni gbogbo ìpínlè wọn.Bakannaa ki wọn ṣe ìpèsè àwọn ibùdó ti àwọn ọdọ ti lè kọ ìṣe ọwọ lẹyin ti wọn ba jade ilé ìwé gíga tí wón kó sì ti rí ìṣe olówó oṣù ṣe.
      Olóyè George tun fi kún ìmọ̀ràn rẹ wipe ki ijoba ṣe ìpèsè ohun amayederun lọlọkan ó jokan sì ilu,ki awon obi le ba fi ifọkanbalẹ tọju awon omo won,ki won si yọnda ọpọlọpọ owo fun eto ìdàgbàsókè ilu, ki wọn kan ma ma da gbogbo owo ti o to si ara ilu si apo ara won nikan.

Comments

Popular posts from this blog

Ọmọlúwàbí Stakeholders Pay Courtesy Visit to Aregbesola, Reaffirm Loyalty to ADC Ideals

APC Chieftain Odukoya Adeyinka Sefiu Resigns, Cites Failed Promises and Unfair Treatment.

FROM BLACKOUT TO BRIGHT LIGHTS: How Dr. Naheem Balogun Rewrote Epe’s Story